Alága ìkọ ẹgbẹ àgbá bóòlù Kwara United, Kunbi Titiloye, àti àwọn adari Kwara United Ki Olukọni ìkọ ẹgbẹ àgbá bóòlù Super Eagles Orílẹ-èdè Nàìjíríà José Peseiro ati ìṣòwọ́ awọn ti wọn jọ kọwọrin kú àbọ̀ sí ìlú Ilorin.
Lẹyìn ìfagágbága nlá tó wáyé láàárín ìkọ ẹgbẹ àgbá bóòlù Orilẹ-ède Sao Tome and Principe àti iko Super Eagles Orílẹ-èdè Nàìjíríà ninu ìfagágbága boomọ ẹsẹ yo ni igbaradi idije ifẹ̀-ẹyẹ ilẹ adúláwọ̀ ti ọdún 2023 ti Orílẹ-èdè Cote D’Ivoire yíò gbàlejò rẹ.
Orílẹ-èdè Agadir ni Morrocco ni ìfagágbága náà ti wáyé ní bí ti anjọnu orilẹ-ède Sao Tome and Principe ti Jáde leku lọwọ pẹlu àmín ayo 10-0 ni Ọjọ Ajé Monday Ojọ Kẹtala Oṣù kẹfà ọdún yi.





Olukọni àgbà fún ikó Super Eagles Orílẹ-èdè yi, Jose Peseiro ati awọn Iko re balẹ bagẹ ṣ’ọwọ alága iko ẹgbẹ àgbá bóòlù Kwara United Kumbi Titiloye ni pápá ko òfurufú ti ìlú Ilorin.
Olukọni ọmọ Orílẹ-èdè Portugal ọhùn yio wo ìfagágbága Nigeria Professional football league (NPFL) ọsẹ ìkẹrinlelọ́gbọ̀n larin Kwara United ati ikọ̀ Sunshine Stars ti ìlú Akure ni ọlá Ọjọ Sunday ni pápá ìseré nlá ti ìpínlẹ̀ Kwara, tí ọwá ni Ilorin.

Alága ìkọ Kwara United Kumbi Titiloye nínú ọrọ rẹ ṣàpèjúwe àbẹwò Peseiro’s bi èròrí ati mu ìdàgbàsókè àti ibojuto tóun ti pipese ọnà tó rọrùn fún adari ijo Kwara United ati sise afihan awọn ogo inu iko náà
Augustine Eguavoen ti o ko ìkọ Super Eagles sódì lo Orílẹ-èdè Cameroon náà wa ṣe abẹwo sí ìko náà lati wo ìfagágbága wọn lẹyìn tí wọn dé lati idije ifeye ile adúláwọ̀ to koja ni oṣù Kejì ọdún yí ni igba ti Kwara United koju Lobi Stars






Leave a Reply