By Ogbeni
Wolii ijọ alaṣọ funfun kan to da abẹla gbigbona soju ara ọṣọrọ ọmọge kan ti gba idajọ ijiya lọwọ ile ẹjọ.
L’Ọjọbọ ni adajọ ran arakunrin Mishack Aguebere lẹwọn ọdun meji lẹyin ti wọn ri pe o jẹbi ẹsun ifipabanilopọ ati ilokulo ọmọde.
Ile ẹjọ majisireeti to wa ni Port Harcourt to jẹ olu ilu ipinlẹ Rivers ni wọn ti ran lọ sẹwọn.
Gẹgẹ baa ṣe gbọ, ọmọ ọdun mẹtala yi jẹ ọmọ to wa labẹ akoso Aguebere.
Niṣe ni ileeṣẹ ọlọpaa fẹsun kan Aguebere labẹ ofin iwa ọdaran Naijria abala okoolenigba ati meji ti ipinlẹ Rivers.
Wọn fẹsun kan pe o fipa lajọṣepọ pẹlu ọṣọrọ ọlọmọge naa to jẹ ibatan iyawo rẹ.
Ọmọ obinrin yi n gbe pẹlu wọn ninu ile ijọsin ijọ alaṣọ funfun wọn to wa ni adugbo Rumuomasi, Port Harcourt.
Majisireeti agba Felicitas Amanze to gbe idajọ kalẹ lori ọrọ yi sọ pe niṣe ni wọn fipa ja ibale ọmọdebinrin yi.
Eleyi si mu ki adajọ fẹdun ọkan rẹ han lori ọwọja iṣẹlẹ ifipabọmọde lopọ ati ifiyajẹ ọmọde to n waye ni Naijriria.
Iwe ayẹwo lati ọdọ awọn oniṣegun sọ pe ohun ti wolii yi ṣe lo mu ki ibale ọmọdebinrin yi faya to si tun ni awọn ipalara miran ti ọlọpaa mnu ba ni ile ẹjọ”
Adajọ Amanze sọ pe ọgbẹ kan ti yoo maa wa lọkan ni nkan ti pasitọ yi ṣe fun ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹtala naa.
Awọn ọmọde to fipa ba lopọ yi jẹ ọmọ ọdun mẹẹdogun, mejidinlogun ati ogun ọdun.
Loṣu Kejila ọdun 2021 dokita kan ni ipinlẹ Delta sọ pe oun fipa ba ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹẹdogun to jẹ ọmọ ọdọ rẹ.
Oludasilẹ ajọ ẹlyinjuaanu Behind Bars Human Rights Foundation, Harrison Gwamnishu, sọ pe eeyan kan lo tawọn lolobo pe iru nkan bayi n ṣẹlẹ.
Gwamnishu sọ pe ṣaaju ki dokita yi to fipa ba ọmọde naa lo pọ, o nioun fẹ yẹ oju ara rẹ wo boya ko tii mọ ọkunrin.
Eleyi jẹ ọkan lara awọn iru iṣẹlẹ yi ton waye lemọlemọ ni Naijiria
Adajọ Amanze to gbe idajọ kalẹ ni Port Harcourt sọ pe awọn ọmọdekunrin ati obinrin nilo aabo topeye lọwọ awọn to n gbero lati ṣẹ aburu si wọn.
#ẹ̀tọ́
BBC Yorùbá





Leave a Reply