ẸGBẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ ÌJÌNLẸ̀ ÈDÈ ÀTI ÀṢÀ YORÙBÁ Ẹ̀KA TI ÌPÍNLẸ̀ KWARA KÍ GÓMÌNÀ ABDULRAHMAN ABDULRAZAQ FÚN ÀTÚNYÀN SÍ’PÒ

Ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè àti àṣà yorùbá ẹ̀ka tí Ìpínlẹ́ Kwara ki Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara Mall. AbdulRahman AbdulRazaq fún àtúnyàn sí pò gẹ́gẹ́ bi Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara fún sáà Kejì.

Àtẹ̀jade gba ti ọ́fìsì ààrẹ ẹgbẹ́ náà, ọ̀gbẹ́ni Adeoye Matiu Bukola ṣe àpèjúwe àṣeyọrí Mall. AbdulRazaq gẹ́gẹ́ bí èsì, sí ìfẹ ará ìlú àti iṣẹ takuntakun tóun ti mímú ìgbàyè gbádùn ìlú ni ọ̀kúnkúndún.

Ninu àtẹ̀jáde náà, o gbé oríyìn fún àwọn ọmọ Ìpínlè Kwara fún ti ètò ìdìbò ti Ààrẹ, Gómìnà àti àwọn aṣojú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tíó wáyé ti o sí lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀.

Ó gbádùn ki àlàáfíà tẹ̀síwájú ni Ìpínlẹ̀ Kwara ati ní Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ó rọ àwọn tí ìlú ṣẹ́ dìbò yàn láti rí ànfààní yìí bí èyí tíó ṣe iyebíye, kí wọ́n sì ní ìfẹ́ ìlú ní óókan àyà wọn.

About Author

Share this News: