KINI AṢA IGBEYAWO NÍ ILẸ YORÙBÁ?
Igbeyawo je nkan pataki ninu asa ati ise Ilẹ Yorùbá, o si je ohun ti ko se fọwọ ro sẹyin ni igbesi aye ọkunrin ati obinrin.
Igbeyawo Ilẹ Yorùbá je ohun ti ko yẹ ki a gbagbe paapaa julo ni aye ode oni ti ikọsile ti pọ ninu igbeyawo. Ki wa ni awọn ohun ti o jẹ ki igbeyawo aye atijọ duro pẹ? Njẹ ilana igbeyawo ti a n lo ni aye isin ni o fa ti ikoraẹni silẹ fi po? E bami kalọ ninu eto yi lati mọ.
Igbeyawo ni Ilẹ Yorùbá ko kin se fun Tọkọtaya nikan ṣugbọn fun gbogbo ẹbi ọkọ ati Iyawo, Igbagbọ awọn Yorùbá ni pe ti eniyan ba n se igbeyawo, kii se ẹni ti o fe ni o se igbeyawo pelu bi ko se awọn ẹbi eni na.
AWỌN IGBESẸ IGBEYAWO NÍNÚ AṢA ATI IṢE ILẸ YORÙBÁ
IGBESE AKOKO: IFOJUSODE
Ifojusode je nkan ti awon ebi ọmọ ọkunrin tabi ọmọ ọkunrin ti o ti to gbeyawo maa n se nipa wiwa ọmo obinrin ti o niwa, ti o lẹwa ti o si wa lati ile ire fun ọmọ wọn lati fẹ tabi ti ọmọ ọkunrin le maa wa fun ara re.
IGBESE IKEJI: IWADI SISE
Awọn ẹbi ọmọ ọkunrin naa yio bẹrẹ si ni wadi nipa iru ile ti obinrin naa ti jade wa. Eyi ni lati mo nipa ẹbi naa boya wọn ni asiri kan tabi egun idile tabi arun kan ti o maa n da wọn laamu ninu ẹbi naa nitori wipe awọn ẹbi miran le ni arun were, kiku ni kekere, warapa ati bẹẹ bẹẹ lọ ti ko si je nkan ti o dara. Wọn a tun se iwadi nipa iyawo ti wọn fẹ fẹ na boya o je eniyan ti won le fẹ wọle nipa mimọ boya o jẹ oni suuru , oninu fufu, Onimọtoto tabi ọbun. Ni igba miran wọn a maa bere lowo alufa(Baba alawo) ki o ba wọn wo ọjọ iwaju awọn mejeeji ninu igbeyawo naa, apẹrẹ ohun ti awọn alufa maa n ri nipe, ọkọ tabi iyawo ko ni ẹmi gigun tabi pe igbeyawo naa yio ni alubarika to pọ ati bẹẹ bẹẹ lo.
IGBESE KẸTA: ALARINA
Alarina jẹ eniyan kan ti o sunmọ ọkọ ati iyawo, eniyan ti yio wa laarin awọn mejeeji fun ibarawonsọrọ nitori pe ni akoko yen ọkọ ati iyawo ko ni tii maa ni ajọsọpọ ọrọ, wọn o maa barawonsọrọ pelu iranlọwọ Alarina. O le jẹ ọrẹ ọkọ tabi ọrẹ iyawo timọtimọ. Alarina yi nio maa royin fun iyawo bi ọkọ rẹ ti se ri, nio si maa jise ẹni kan fun eni kẹji, eyi ni lati mu gbogbo igbese na lọ geerege titi ti yio fi fi ọkọ ati iyawo han ara wọn.
IGBESE KẸRIN: IJOHẸN TABI ISIHUN
Ni ipele yi, ko si inilo fun alarina mọ laarin ọkọ ati iyawo. Ọko ti mọ oju Iyawo, Iyawo naa ti mo ọkọ rẹ. Nibi igbese kẹrin yi ni ọmọ obinrin yio ti gba lati je iyawo ọkunrin, lai ti gba oruka (gẹgẹ bi afẹsona), sugbọn ọkunrin naa gbọdo san “Owo Isihun” fun obinrin naa pe o ti jẹ ni O.
IGBESE KAARUN: IDANA
Leyin ti ọmọ obinrin naa ti gba lati di iyawoLeyin ti ọmọ obinrin naa ti gba lati di iyawo ọkunrin naa, Ọkunrin naa yio wa so fun awọn obi rẹ pe ohun ti ri ododo kan ti o rẹwa ti ohun fẹ ja ninu ile kan. Baba ọkunrin yio wa bẹrẹ si ni se igbaradi lati lọ tọrọ ọmọ obinrin lọdọ awọn obi rẹ. Ni igba akoko ti won ba lọ yoju nile awọn obinrin naa, Baba ọkọ ati awọn ebi die ni o losi ile awọn ọmọ obinrin laarọ kutukutu. Leyin ti Baba iyawo ba ti gba lati fun wọn ni ọmọ, yio wa fi ye wọn wipe ohun nikan kọ ni ohun bi ọmọ naa(Igbagbọ wọn nipe gbogbo ilu loni ọmọ). Leyin eyi ni yio wa fun wọn ni ọjọ kan pato fun eto mọmi n mọ ọ ti gbogbo ẹbi yio wa nibẹ.
Obi awọn ọmọ mejeeji yio wa maa pe gbogbo awọn ẹbi wọn lati sọ fun wọn nipa ẹto mọmi n mọ ọ. Nibi ẹto yi ni gbogbo ẹbi yio ti mọ ara wọn, wọn le se ni owurọ, wọn si tun le se ni irọle. Awọn ẹbi ọkọ yio si gbe awọn ẹbun orisirisi lọ fun momi n mo o.Awọn ẹbun yi ni a n pe ni ERU IYAWO
Awọn ẹbun bii;
Oyin, ireke, iyo( Ki ibagbepo won le ni adun to po)
Obi ati Orogbo(Ki awon mejeeji le dagba ki won dogbo)
Ataare( Ki Iyawo le bi omo pupo)
Ẹpo pupa( Ki igbeyawo naa lẹ jẹ irorun lai si Ija)
Ọpọlọpọ Isu, Eso ati awọn ounjẹ miran fun awọn ẹbi iyawo
Owo ori( Ti iyawo ati awọn owo kekeke miran fun awọn mọlẹbi
Ẹmu ati awọn ọti miran lati fi se ayẹyẹ na.
Ẹni ti o dagba ju ninu ẹbi Iyawo yio fi ọmọ obinrin naa le ẹni ti o dagba ju ninu ẹbi ọkọ lọwọ, ti wọn o si maa ka ohun ti wọn ko gbọdo se fun ọmọ won, gẹgẹ bi eewọ ati ofin, bi apẹre “Pe wọn ko gbọdo naa ọmọ won tabi fi iya jẹ, Pe ọmọ wọn kii je awọn ounje kan tabi imiran. Leyin eleyi ni iyawo yio bẹrẹ si ni ko gbogbo ẹru rẹ si oju kan lati maa mura ile ọkọ rẹ.
IGBESE KẸFA: IGBEYAWO
Igbeyawo gẹgẹ bi orukọ rẹ, tumo si gbigbe Iyawo lọsi ile ọkọ. Ọjọ igbeyawo yi maa n je ọjọ ti o maa n larinrin pẹlu dida lori bi awọn ẹbi mejeeji se lowo to, Ounje maa n wa lọpọ yanturu, olorin yio maa korin ti awọn eniyan yio si maa jo
To ba wa di ni ọjọ rọ(Irọle), ni ọjọ igbeyawo, Iya iyawo yio pe ọmọ rẹ lati fun ni ọrọ isiti bi wọn se n gbe ilẹ ọkọ, eni ti o dagba julọ ninu ẹbi, iya ati baba yio wa se adura fun. Lẹyin eleyi awon ẹbi iyawo yio maa sin losi ilẹ ọkọ re.
Ki iyawo tuntun to de ilẹ ọkọ, ọkọ gbodo jade nile nitori pe eewo ni fun iyawo asẹsẹ gbe lati ba ọkọ rẹ nile. Kete ti iyawo ba de ile ọkọ re, ki o to wole, wọn o bu omi tutu si iyawo lese ki ara le tu ninu ile ọkọ re. iyawo yio losi odo ẹni tio dagba ju ninu ẹbi ọkọ re fun adura.
Ni aye atijo, awon Yorùbá pataki obinrin ti ko ti mo okunrin ni fife, Ti o ba wa di ale ojo igbeyawo, Ọkọ gbọdo ba Iyawo re ni ajọsepo lati mọ boya iyawo re si wa ni odidi(bọya koi ti mọ ọkunrin). Ti ọmọ obinrin na ba ti mọ ọkunrin, ọkọ ti o gbe ni iyawo le kọ silẹ, yio si da pada si ọdọ awọn obi re, awọn ti wọn sin iyawo wa si ile ọkọ ni won o lọ jise fun awọn obi rẹ. Ti awọn ẹbi ọkọ yio si fi awon nkan ranse lati fi se ami pe won ko ba ọmọ wọn nile. Awọn nkan bi Agbe ẹmu abo, Korofo ishana ati bẹẹ bẹẹ lo, eleyi ti yio maa je idojuti fun awọn obi iyawo naa. Sugbon ti ọkọ ba ba iyawo rẹ nile, iwuri ni yio je fun awon obi iyawo ti awọn ẹbi ọkọ yio si fi ẹbun orisirisi ranse si awon obi iyawo pe won fun awon ni omo to pe.
Lẹyin igbeyawo, ohun ti gbogbo ẹbi, ara ati orẹ yio maa reti nipe ki iyawo fi inu soyun ki o si bimo lẹyin osu mẹsan nitori pe awọn Yorùbá pataki omo bibi gan.
Eleyi ni AṢA IGBEYAWO NÍ ILẸ YORÙBÁ ti o yatọ si ti ode oni. Ohun si ni okunfa ati idi ti igbeyawo aye atijọ fi maa n pẹ, pẹlu ikoraẹnisilẹ die.
#blockculture





Leave a Reply