Olùdíje sí ilé ìgbìmọ̀ aṣofin àgbà fún ẹkùn ìhà gúúsù Ìpínlè Kwara labẹ àsìá ẹgbẹ òṣèlú Social Democratic Party (SDP) Ọjọgbọn Wale Sulaiman sọ pé òun to bi èrò n’gba ohun láti dije lo ṣ’oju ìhà gúúsù Ìpínlè gúúsù n’ipe kò sí ifi ara jin lati soju ni agbègbè náà, o ni ìhà oun nilo lati ni aṣoju to lè pè bi oun tin ri ki o lè mú àwọn ènìyàn àgbègbè náà dé ibí gíga.
Wale Sulaiman to jẹ ọjọgbọn lẹka ètò ìlera to n’risi iṣẹ abẹ awon èyà ara kan, sí tún jẹ olú bá da’moran pàtàkì lórí ọrọ ìlera sí Gómìnà Abdulrazaq nígbà kan ri sọ èyí ní ibi ètò ìfi ọrọ we’rọ, fori okòó sọodúnrún to wáyé pẹlu ẹgbẹ akọ̀ròyìn lori ìtàkùn ayelujara ẹka ti’pinle Kwara, (ASKOMP) Association Of Kwara Online Media Practitioners.
Ọjọgbọn nipa ètò ẹkọ tó tun fi ara re jin fún ọpọ iṣẹ ọmọnìyàn pàápàá fún aseyori ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara ati ni tíìbu tòóro orile-ede Nàìjíríà tofi mọ òkè òkun, òun sì tún ni o ni sábàbi ire fún imu pàdà bo sípò ibùdó ọsijin ti ìpínlẹ̀ Kwara to ti wa ni ikorita pọo láti bí ogójì ọdún sẹyìn, imú pàdà bọ sípò ibùdó yìí lómú Ìpínlè Kwara wa ní ipò kẹta lara awọn ipinlẹ to gbaradi dènà àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19.
Ọṣe agbekalẹ àjọ to’nf’ara jin fún ẹdá ọmọnìyàn tán sí nṣe iṣẹ abẹ ati ètò ìlera fún ìhà gúúsù Ìpínlè Kwara.
O sọ nípa àwọn ìlànà rẹ fun ìhà gúúsù Ìpínlè Kwara, nínú ọrọ rẹ, o ni agbègbè náà kòi tíì je anfani asojú ni sáà iṣejọba àwa arawa to síi je esi ọnà angba yan awọn adari wa tabi ona ti wọn fi nyàn adari fún wa.
B’oba jẹ ti ajọṣepọ to’nbe láàárín oun ati ẹgbẹ òṣèlú APC lateyin wa, o ni ko ba mọ́ sí ìdí ati ni èrò n’gba ati dije sójú awọn èyán ìhà gúúsù Ìpínlè Kwara, to ri rẹ ni òhun fi wá anfani ati rí daaju pé àwọn èyán jẹ anfani sí ṣe ojú wọn daradara.
O ṣe àpèjúwe ọpọ adojuko ti orile-ede yìí nkoju bi ipenija ètò àbò èyí tí kò yọ ọpọ ìjọba ìbílẹ̀ to wa ni ìhà gúúsù Ìpínlè Kwara sí lẹ, gẹgẹ bí ènìyàn ti o ti fi ara rẹ jin lati sìn ilu tó sì jẹ ikan gbóògì lara afojusun ìjọba, O ni oun o pèsè ọnà ti yíò mu ọrọ ba awọn èyán ohun, pèsè ọpọlọpọ ànfààní nipasẹ iṣe ati ọpọ ohun imu ayé gbedemuke ti yíò mu awọn eniyan le fi ọwọ ho’ori. O tọka sí gẹgẹ bí èyí ti yíò mu opin dé bá ọpọ adojuko ati ipenija ètò àbò, o ni nipasẹ ètò asofin yìí ni ọpọ nkan yi ṣe lè ṣeéṣe.
O ṣàpèjúwe bi Nàìjíría ṣe nkunaa ni pa lọpọ ọnà, ni ijoba àpapọ̀, ijọba Ìpínlè to fi dori ìjọba ìbílẹ̀, o ni ọ̀rọ̀ aini ètò àbò yi níí ṣe pẹ̀lú ọpọ àwọn nkan bi àìní àyíká to mú yan, aini ètò fún iṣẹ oun òṣì ati bẹbẹ lọ.
Oni oluwa’di to mọ nipa agbegbe re ati awọn eniyan rẹ nípa ìṣèlú ni yíò fún àwọn ìlú ni oun tán nilo ti ìlú osi le tọkasi.
O so pé aseye lohun ọṣe níbi ètò Ìdìbò ọdún 2022, pe ko síi ohun ti yíò dáa òun dúró, ni torípé awọn olùdíje ìmí to kun tàwọn jan wa ipo náà nlá ọmọ ẹkùn oun ti gbe yewo tán sí mo ohun ti wọn wọn.
Nípa ipò asojú ẹkùn ìhà gúúsù Ìpínlè Kwara, o ni bí oun ba jáwé Olubori, oun o je olórí gbogbo ènìyàn, ti awọn ìlú osi ni anfaani ati rí òun ni igba kìígba.
Síwájú síi, pe ọpọ olóṣèlú lo wa ipò pẹlu gbogbo tan ni, o ni agbára wa lọwọ àwọn ènìyàn láti yan ẹnití wọn wá.
Ni pa ètò idibo odun 2019, Ọjọgbọn Wale Sulaiman ni “OTOGE odun 2019 ni ìbẹrẹ ayípadà ọtun lẹka òṣèlú ni ìpínlè Kwara, o ni o na síi yin, o ni opin ti dé bá sáà náà, ti awọn kan yi o ma pa àṣẹ ohun ti àwọn olóṣèlú yíò ṣẹ, o ni eyi ni agbùdò fi òpin sí.






Leave a Reply