Advertisement

Ìdẹ́yẹ sí ṣe ASUU : Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de ìfẹ̀hónú hàn ní Eko, Ilorin àti Imo

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fẹ́ gùnlé ìwọ́de oní àláfíà náà nítorí tí oṣù mẹ́ta ti pé tí ASUU ti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì, tí àwọn NASU náà sì ti kún wọn.Bákan náà ni kò jọ wí pé ìyanṣẹ́lódì náà yóò wá sópin láìpẹ́ tí èyí sì ń kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lóminú.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó gba orí ayélujára kan, ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Karùn-ún, ọdún 2022 ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko yóò péjọ sí orítà ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ti ìjọba àpapọ̀ ní Yaba ní aago mẹ́jọ òwúrọ̀ fún ìfẹ̀hónúhàn ti wọn.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìlú Ilorin yóò péjọ sí ẹnu ọ̀nà ilé ẹ̀kọ́ náà fún ìwọ́de.

Ní orí ẹ̀rọ ayélujára Twitter báyìí, igbe kí ìjọba àti ẹgbẹ́ ASUU wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ìyanṣẹ́lódì náà ló gba orí rẹ̀ kan.

#BBCYoruba

About Author

Share this News:

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *