Advertisement

Ìjàmbá iná Ọja Alanamu: Saliu Mustapha ṣe ètò owo fún sí sọ ọjà náà dọtun

Kéde ètò àkànṣe owo fún àwọn tó ní ìsọ ni ibí iṣẹlẹ iná náà

Turaki Ilorin Emirate, to tun je olùdíje fún ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní ẹkùn ìhà àrin gùngùn Ìpínlè Kwara labẹ àsìá ẹgbẹ òṣèlú All Progressive Congress (APC) ti pàṣẹ ki awọn òṣìṣẹ́ o bẹrẹ iṣẹ atun ṣe ni kíákíá sí àwọn ìsọ ti ó f’ara káṣá ni ibi iṣẹlẹ iná tó wáyé ni ọjà Alanamu ni Ilorin tíó jẹ olú ìlú fún Ìpínlè Kwara.

Ìṣẹlẹ iná òun tó jó ọpọ dúkìá ti eye rẹ tó mílíọ̀nù mẹjọ náírà lo búyọ ni afẹmọjumọ ọjọ àjé.

Gẹgẹ bí ẹlẹrìí tí iṣẹlẹ náà ṣe ojú rẹ ṣe sọ, ó ní iṣẹlẹ ìjàmbá iná ohun bẹrẹ bi ọwọ ago mẹrin afẹmọjumọ ti o sí kọlu ìsọ ti ó lé ní mẹwa, àwọn ṣobu ti ókun fún oríṣiríṣi ọjà bí aṣọ, mansini ìránsọ, Amúlétùtù, Ọtí elérìndòdò ati bẹbẹ lọ ti awọn ẹṣọ panápaná sí dòólà ìṣẹlẹ náà.

Títí di Ọjọ etí (Friday) awọn àwọn tó lù’gbàdè iṣẹlẹ náà sí nkan awọn ohun ti wan pàdánù ninu iṣẹlẹ náà.

Lórí àbẹwò ìbánikédùn náà, Saliu bẹ ìsọ mọkànlá ti iná tí ṣọṣe oun èyí tí Balogun Alanamu ti ilorin Dr Usman Abubakar Jos, pe kí o le mọ ìwọn iṣẹlẹ náà.

Mustapha tí ògún lọ́gọ̀ awọn ololufẹ ati awon Afénífére ṣe ni kabọ sí ibí iṣẹlẹ náà jẹjẹ pe ni ọjọ Sátidé ni iṣẹ yíò bere ní ibẹ.

Saliu ni kí Balogun Alanamu o ṣe agbekale ìgbìmò ti yíò ba àjọ ohun jòkó àpérò láti ṣe ètò owo ọfẹ fún àwọn tí wọn lù’gbàdè láti ri pe wọn padà sórí ẹsẹ wọn lati bẹrẹ oko òwò won padà.

Balogun Alanamu dupẹ lọwọ Saliu fún yiyara láti fi ojú hàn latari iṣẹlẹ làlúrì náà.

O gbé òsubà ràndẹ̀ fún latari lilawo ati alanu tíó jé, e yi je awon oun to ti ṣe tíó wà ṣaju dara pọ mọ òloṣèlú.

Ninu atejade kan tíó ọ ṣaju wáyé, ti Saliu mustapha fi sita ni ọjọ Isẹgun Tuesday ba Balogun Alanamu ati gbogbo awọn agbègbè wọn lórí iṣẹlẹ náà

About Author

Share this News:

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *