Wákàtí diẹ sẹhin ni àwòrán foto Mínísítà tẹlẹ rí fún eré ìdárayá ati idagbasoke ọdọ lórílè-edè yi, Mallam Bólájí Abdullahi lu jáde lori ìtàkùn ayelujara to ṣe àbẹwò sí gbajugbaja onísòwò tosí tún jẹ èkàn lẹgbẹ òṣèlú APC, Amb. Abdulfatai Yahaya Seriki- Gambari Oludije tẹlẹri sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà fún ẹkùn ìhà àrin gungun Ìpínlè Kwara labẹ ẹgbẹ òṣèlú APC.
Mallam Bolaji Abdullahi ti oti figba kan fẹ dije du ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ yìí ló ṣe abẹwo ti won fi sọ ri ayẹyẹ ọdún iléyá sí kànrì lẹgbẹ òṣèlú ohùn.
Àlàyé àti ohun tí ari kojọ ni wípé àwon méjèèjì ṣe ìpàdé bonkẹlẹ làrin ara wọn ti ohùn ti wọn sọ kò sí hàn sí àwọn akọ ìròyìn titi igba ti a nṣe akojọpọ ìròyìn yìí.
Arigbọ pé Yahaya Seriki-Gambari fí ìmọ ore hàn sí Bolaji Abdullahi olùdíje sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà fún ẹkùn ìhà àrin gùngùn Ìpínlè Kwara labẹ ẹgbẹ òṣèlú PDP to ṣe àbẹwò sí ati awọn t’án jọ kọwọrin.

bí kò bai ṣe ẹgbẹ òṣèlú wọn tó yàtọ ní, ọmọ ẹkùn kan ni wọn, è yìí ló sì bí ọpọ ọrọ ni igboro lórí oun to le p’awọn pọ lásìkò òṣèlú ti awàyi pẹlu bi awọn méjèjì ko ṣe sí ní ègbé kàn náà.
Ọpọ àwọn ọmọ ẹgbẹ òṣèlú APC ni ìhà àrin gùngùn Ìpínlè Kwara lo ti wá nínú ìfòró ọkàn tán sí n’bẹrù, bẹẹni ọpọ àwọn eyan náà sì nsọ orisirisi ọrọ ni pa ètò idibo to nbọ papa julọ ni ìhà àrin gùngùn Ìpínlè Kwara.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn nbọ lórí ẹ






Leave a Reply