Advertisement

Sa’adatu Modibbo Kawu, a ri tọ́ka sí pípé ati ojúlówó obinrin takuntakun ti oòrùn rẹ sí nràn.

Láti ọwọ Oluwatoyin Luqman Boladale

Irandiran yíò bi mí, bí mo bá kọ láti jẹ́wọ àti láti gbé òsubà ràndẹ̀ fún èkàn, ènìyàn pataki, akíkanjú, obinrin takuntakun, ọmọ bíbí ìlú Ilorin yìí Hajia Sa’adatu Modibbo Kawu lórí ayẹyẹ ọjọ ìbí rẹ.

Pẹlu gbogbo ìlàkọjá, adojukọ àti òhun t’oju ri, látàrí èrò n’gba ati sìn ilu tayọ iwọ awọn obìnrin, sibẹsibẹ ó farahàn gẹgẹ bí èkàn, ènìyàn pataki, akíkanjú, obinrin takuntakun ìran yìí ní ìpínlè Kwara tó tíì tayọ làrin awọn ẹlẹgbẹ rẹ nípa ilowosi tíó kọjá iwọn awọn obìnrin ní ìpínlè Kwara.

Ó kó ipa takun-takun lórí imúkúrò aibikita, aikọbi ara sí ati àìní ìtara awọn obinrin lórí ọrọ òṣèlú tíì èyí sì tí mú kí ọpọlọpọ obinrin o ta kìíjii láwùjọ awọn obinrin ni ipinlẹ Kwara.

Awà ni awọn ikorita kan ni Kwara, ti a rò pé ẹ̀tọ́ obinrin kò ju ohun ìdáná lásán-làsàn lọ ní kíṣìnì, àmọ́ Hajia Sa’adatu Modibbo Kawu tíì jẹ oní sábàbí ire fún ọpọlọpọ obinrin lati yọ wọn nínú oko ẹrú ìgbàlódé n’ipasẹ onírúurú ìdásí atí ìlani lọ́yẹ̀ itagbangba.

Bẹẹni irandiran yíò bi mí, bi mo bá kùnà láti gbé fún, fún ipa ìyá tíì o to nko láwùjọ awọn obinrin ni ìpínlẹ̀ Kwara.

Mo wá fi àsìkò yìí, nbá yọ fún ayẹyẹ ọjọ ìbí rẹ, mọ sí nki fún gbogbo ohun ti o ti ṣe.

Ki ọlọrun nínú áanu rẹ tẹ si wájú láti máà bùkún tayọ gbogbo ìlàkọjá, fún ni ore-ọfẹ lóri adawo leṣe rẹ gẹgẹ bí ọlọ́danni, ki osi da àbò bó, ki o sí gbé ga ni ìkọkọ ati ni gbangba lori gbogbo ifekufe.

About Author

Share this News:

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *