Pè fún ìbáṣepọ̀ ni igbaradi ìpolongo
Olùdíje sí ipò Gómìnà labẹ àsìá ẹgbẹ òṣèlú PDP Alhaji Shuaib Usman Abdullahi ni Ọjọ ìsinmi ṣe ìpàdé àpérò pẹlu agbarijọpọ ẹgbẹ àwọn akọ̀ròyìn lórí ìtàkùn ayélujára (ASKOMP) ni igbaradi ètò ìdìbò apapọ ọdún 2023.
Yaman ní’bí ifi ọrọ we ọrọ èyí tíó wá yé ní gbàngàn ile itura Emirate Hotel ni Ilorin sọ awọn èròngbà rẹ ṣáájú àfihàn ibẹrẹ eto ìdìbò ẹgbẹ PDP tíó wáyé ní ọjọ Ọjọ́rú Wednesday.
Nínú ọrọ rẹ, o ni, aní èròngbà to lè mú ìpínlè Kwara wa lára àwọn ìpínlẹ̀ tí yíò mọ pa owó wọ le lábélé bi ìpínlè Eko ati awọn ìmí.
Oseni láanu bi ìjọba ìpínlè Kwara ṣe ya owo, tan sí san gbèsè. Èyí o ṣe gb’ọkan le, nígbà tí ìjọba o pèsè àwọn o na tí a lè gbà pa owó, òwú ṣiṣe nikan gan tó láti fi wa ohun ti a nilo lati mu ohun gbogbo bọ sí po.
Olùdíje sí ipò Gómìnà labẹ àsìá ẹgbẹ òṣèlú PDP ṣe ìlérí ati mu awọn ètò ìdàgbàsókè yi kárí gbogbo ìpínlè Kwara.
Gbogbo ẹkùn to sọ ìpínlè Kwara ró (Ẹkùn Ìhà Gúúsù, Àríwá ati ìhà Arin gùngùn ni yíò jẹ igbadun ìpín dọgbadọgba iṣẹ ìjọba wa. Lọ wọ yìí, ati ba ọpọ àwọn ilé iṣẹ sọrọ, ile iṣẹ tón pèsè oúnjẹ àti ti ìmọ̀ ẹ̀rọ.
Gbogbo wọn ti ṣe tán ati gbé ile iṣẹ wọn wà ìpínlè Kwara, ile iṣẹ bi DANO, Peak Milk ati ọpọ bẹẹbẹ lọ. A wo ona ati r’ọgun s’ápá awọn Ọ̀dó lójú náà àti ṣiwọn lójú sí àwọn ohun tó tọ́ a ngbà ṣe nkan.
Yaman sọrọ nípa àjọṣepọ̀ tíó wa larin ohun ati Gómìnà Abdulrasaq AbdulRahman, o ní kó kun oju oṣuwọn lati mu ọpọ àbá wá sí imuṣe.
Mo ti ba Gómìnà Abdulrasaq AbdulRahman sọ ọpọ ero tíó dara ṣugbọn míò rò pé o ni oye awọn ẹrọ daradara wọnyi, mo ni igbagbọ pe eyi lo mu wa wà nihin lóni, bi èyán o ba ni eni tíó kun oju oṣuwọn lati ẹrọ gidi wá sí imuṣe. Ènìyàn le kùnà.
Ni ìgbà tíó f’èsì sí ọrọ ti awọn ọmọ ẹgbẹ ASKOMP sọ lati ma ṣe awọn agbe jade ìròyìn fún àwọn ọmọ ìpínlè Kwara, Yaman pe ibaṣepọ to l’orin pẹlu ẹgbẹ náà kí ìpolongo oun le kesejari.
Ṣáájú ni alága agbarijo ẹgbẹ àwọn akọ̀ròyìn lórí ìtàkùn ayélujára (ASKOMP), Saliu Shola Taofeek ni ẹgbẹ àwọn akọ̀ròyìn nbá awọn oludije fi ọrọ we ọrọ lati mo ohun ti wọn gbé dání lati le ma gbe jade fún àwọn ọmọ ìpínlè Kwara lẹkunrẹrẹ.





Leave a Reply