Advertisement

Mi oìṣe alagbateru ẹsìn tabi ẹni tíì ongbe ẹṣin sórí – Ọjọgbọn Ọba AbdulRaheem

Olùdíje du ipò Gómìnà labẹ àsìá ẹgbẹ òṣèlú The Nigeria People’s Party (NNPP) ni ìpínlè Kwara, Ọjọgbọn Shuaib Ọba AbdulRaheem sọ wípé òun kì ṣe ẹni tíì o nṣe agbateru ẹsin tabi olodoni tíì o nṣe koriya fún ẹlẹyà-mèyà.

Ọjogbọn AbdulRaheem sọ di mídọ̀ ni ọjọ ajé ní ibi ifi ọ̀rọ̀-wérò pẹlu agbarijọpọ ẹgbẹ akọ̀ròyìn lórí ìtàkùn ayélujára, Association Of Kwara Online Media Practitioners (ASKOMP) atiawọn èkàn ìlú lẹka ètò ìròyìn ni gbọgán iṣe ayẹyẹ Golden Sand Hotel, Ilorin.

Gíwá àgbà tẹlẹri fún ilé ẹkọ gíga fasiti ilu ilorin wípé èròngbà oun ni lati du ipò Gómìnà ni lati mu ìdàgbàsókè bá ìpínlè Kwara ati lati mu ayé gbedemuke fún àwọn ọmọ ìpínlè Kwara.

Miò mu wiwa ipo náà ni dandan ṣugbọn ẹro ngba mi ni lati bù ìyí ku àwùjọ nipa ìdàgbàsókè tíó ni ìtumò ba Ìpínlè Kwara, awọn kan ro pé mo tíì dàgbà jù láti darí ipinle Kwara, mo ní iran ti o tayọ fún ìdàgbàsókè ìpínlè Kwara, Ìpínlè Kwara ni lo ìdàgbàsókè pàtàkì lẹka ohun amayederun ati idagbasoke ije ọmọ ènìyàn.

Mo dàgbà ni ìpínlè Kano, Ìpínlè òun sì ti rí ìdàgbàsókè pàtàkì, lenu ọpọ ọdún sẹyìn.O ni, ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP nikan lo le gbà Nàìjíría lọwọ ìjọba burúkú ati ìjọba jegudujera.

O wi pé, ẹgbẹ òṣèlú NNPP ti ta kàngbàn, ta ẹ̀ka kiri dé ibi kan, o ni ẹgbẹ òṣèlú méjì péré n’odari wa ni orile-ede Nàìjíríà (APC ati PDP) awọn irú èèyàn kàn náà sì ni wọn, awọn aláìní èrò.Kwara ati orile-ede Nàìjíríà ko le ni ìtẹ̀síwájú bi a ko ba ni eni ti awọ rẹ ká oju oṣuwọn tíì o sí ní iran tíì o tayọ tíì o le darí wa.

Ní pa bi o ṣe ku ro ni APC lọ SDP ati bi o ṣe ndije labẹ àsìá ẹgbẹ òṣèlú NNPP, Ọjọgbọn Oba AbdulRaheem ni a o kuro ni ibi kan bọ sí ibìkan, nítorí ìṣòro orile-ede yi ko ni ṣe pẹlu ẹgbẹ òṣèlú biko ṣe irufẹ èèyàn tí yóò dárí wa, èyí ló ṣe baba nbari.

Lati je igba ojúmọ̀, esi iṣẹ takuntakun ti eyan ti se ni isemi ìgbìyànjú ẹda, bi a ba fún eyan ti ko ní iran ni ànfàní láti darí wa, eni náà yíò kùnà, bi mo ṣe kuro ni ibikan bọ sí ibo mi, torí pé mo ká oju oṣuwọn ni.Ọjogbọn AbdulRaheem fikun pe, Ìpínlè Kwara wa leyin pátápátá ṣugbọn o ṣe ìlérí láti mú ètò amayederun tíó ni elegbe bá ìpínlè Kwara, bi wọn ba dibo yan ohun.

About Author

Share this News:

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *